Psalmu
128:1 Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o bẹru Oluwa; ti o rìn li ọ̀na rẹ̀.
128:2 Nitoripe iwọ o jẹ iṣẹ ọwọ rẹ: ibukun ni fun ọ, ati
yio dara fun ọ.
128:3 Aya rẹ yio dabi ajara eleso ni ẹba ile rẹ: tire
awọn ọmọ bi eweko olifi yi tabili rẹ ka.
128:4 Kiyesi i, bayi li ao bukún fun ọkunrin na ti o bẹru Oluwa.
128:5 Oluwa yio busi i fun ọ lati Sioni wá: iwọ o si ri ire
Jerusalemu li ojo aye re gbogbo.
128:6 Nitõtọ, iwọ o ri awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati alafia lori Israeli.