Psalmu
120:1 Ninu ipọnju mi emi kigbe pè Oluwa, o si gbọ mi.
Daf 120:2 YCE - Oluwa, gbà ọkàn mi lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan.
120:3 Kili ao fi fun ọ? tabi kili a o ṣe si ọ, iwọ
ahọn eke?
120:4 Awọn ọfà mimú ti awọn alagbara, pẹlu ẹyín igi juniper.
Daf 120:5 YCE - Egbé ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meseki, ti mo si joko ninu agọ Kedari!
120:6 Ọkàn mi ti gbe pẹlu ẹniti o korira alafia.
Daf 120:7 YCE - alafia ni mo wà: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ogun ni nwọn.